Ifeoluwa Ojelabi
Yoruba
Twitter: @ifeoluwaOjelabi
LinkedIn: http://linkedin.com/in/ifeoluwa-oshodi-b644b156

Publications:

Ajeigbe, A.K., Uche, C.L., Ojelabi, I.H., Olukoyejo, O.E., Jokanola, O.J., Odun-Afolabi, O.O., and Idogun, E.S., 2023. Influence of Female Gender on the Prevalence of Metabolic Syndrome in Normal Weight and Overweight/Obese Adults in South South Nigeria. Nigerian Journal of Health Sciences, 23(1).

Ajeigbe, A.K., Adedeji, T.A., Ajose, O.A., Jeje, O.A., Smith, O.S., Bello, M.B., Olukoyejo, O.E., Jokanola, O.J., Makinde, R.A., Ojelabi, I.H. and Odun-Afolabi, O.O., 2021. Pattern and Sero-prevalence of Covid-19 Screening among Patients in a Tertiary Hospital, Southwestern Nigeria. Am. J. Biomed. Sci, 13(4), pp.184-191.

Ojelabi, I.H., 2017. Association between female reproductive factor and cardiovascular risk. Clin Chem Lab Med 2017; 55, Special Suppl, pp S1506 – S1630.

Ojelabi, I.H., in press, Biochemical and Clinical effects of contraceptives on women of reproductive age in Ile-Ife. National Postgraduate Medical College of Nigeria.

Ojelabi, I.H., in preparation, Evaluation of unconscious children with neuro-infections using Metagenomics studies in comparison with the current diagnostic tools and subsequent outcomes in Nigeria.
About me:

I am a chemical pathologist with subspeciality in Molecular diagnostics, i study molecular biology and genomics as a tool to be adapted to genomics of communicable i.e infections and non communicable diseases which entails, human and cancer genomics, this is to investigate and provide diagnosis as early as possible for appropriate treatment in humans , my interest is to provide personalized medicine with analysis of individual genome.

I grew up in the ancient city of Oshogbo, its domicile in Osun state southwest of Nigeria. It is majorly a Yoruba speaking part of the country one othe the six Yoruba speaking states. Education is of uptomst importance and many have been trained in sciences, art , social sciences and cultural studies. The state also house Ile-Ife, known as the source of Yoruba lineage, with all the ancient art works in moseums and traditional buildings.

We had science laboratories in my school that caught my fancies and endeared me to sciences, also when a child is intelligent, we are made to believe sciences is for you and every one is motivated to do well enough to be seen as science worthy in my secondary school. i love chemistry and biology and longed to study chemical or computer engineering.

I studied medicine and surgery in Obafemi Awolowo University Ile-Ife, Osun State, i had scholarship from my home state , Ondo State all thru my stay in medical school, this kept me encouraged as i was eager to put in my best to retain my scholarship status. I earned my MSc in Clinical Pathology from the University of Lagos , then had my residency training in Chemical Pathology at ObafemiAwolowo University Teaching Hospital, Ile-Ife and currently i am in the Molecular biology and genomics Phd program at the Redeemers University Ede, also in Osun state (ACEGID).

My interest in women and children welfare informed the researches in metabolic medicine and molecular diagnostics solution , that is the use of technology (next generation sequencing ) and data science to provide medical solutions as the conventional diagnostic tools seems medically unreliable, with these new tools of dignosis, early and appropriate treatment which will prevent complications are gotten, more so there are frequent new discoveries which amazes me always.


Learn more about me:

There is always a purpose to our exixtence, my drive in life is to fulfill my own purpose, and this i am doing folllowing the step by step leading of He that created the purpose and created me.

My advice for young people:
If Marie Curie could make discoveries and we are still making new ones now, it is sure there are many more to be made, so the young ones should be eager to make them happen.

Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ ní fún àwọn ọ̀dọ́?
Tí Marie Cuire bá le ṣe àwọn àwárí tí àwa náà sì ń ṣe àwọn àwárí tuntun báyìí, ó dá mi lójú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ló wà láti ṣe. Nítorí náà kí àwọn ọ̀dọ́ múra láti mú kí àwọn iṣẹ́ náà ṣe é ṣe.
Nípa mi:

Mo jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn òyìnbó nípa fífi kẹ́míkà ṣe àwárí àwọn orísun ààrùn tí ó sì se pàtàkì nipa fífi ìmọ̀ ìwádìí mòlíkúlà mọ ohun tí ó ṣe okùnfà àwọn àìsàn náà. Mo ṣe ìwádìí Mòlíkúlà Biology àti Genomics gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti ṣiṣẹ́ lórí genomics àwọn ààrùn tí ó le ràn àti àwọn ààrùn tí kò le ràn tí ó sì ní í ṣe pẹ̀lú genomics àwa ènìyàn àti ti jẹjẹrẹ. Èyí ni láti ṣe ìwádìí àti láti pèsè àyẹ̀wò ní kíákíá kí á sì ṣe ìtọ́jú tí ó yẹ fún àwọn ènìyàn. Ìfẹ́ ẹ̀ mi ni láti pèsè òògùn tí ara-ẹni pẹ̀lú ìtúpalẹ̀ jíínì ènìyàn.

Mo dàgbà ní ìlú Ìṣèǹbáyé Òṣogbo. Ó wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ìwọ̀ oòrùn gúńsù Nàìjíríà. Ó jẹ́ abala kan nínú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí a ti ń sọ èdè Yorùbá jùlọ, ọ̀kan nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fà tí ó ń sọ Èdè Yorùbà ni ìlú Òṣogbo jẹ́. Nínú Ìpínlẹ̀ yìí náà ni Ìlú Ilé-Ifẹ̀ tí í ṣe orísun ìran Yorùbá wà, pẹ̀lú gbogbo àwọn iṣẹ́ àràǹbarà àṣà àti ìṣe. Ilé ìkóǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé pamọ́ sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilé àṣà tó ní kì mí. Èkó jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a sì ti kọ́ nípa ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì, Art, Social Science àti Àṣà.

A ní àwọn yàrá ì kó nǹkan ìṣiṣẹ́ sáyẹ́ǹsì sí ní ilé-ìwé mi èyí tí ó fa ìfẹ́ ọkàn mi tí ó sì mú kí sáyẹ́ǹsì wù mí láti ṣe. Àti wí pé, bí ọmọ kan bá jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, a mú kí á gbàgbọ́ pé Sáyẹ́ńsì ni ó dára fún un a sì máa ń ru gbogbo ọmọ sókò láti ṣe dáradára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí a ó fileè rí i gẹ́gẹ́ bí ẹnití ó yẹ láti kọ́ nípa ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì ní ilé ìwé girama mi. Mo fẹ́ràn Chemistry àti Biology, mo sì làkàkà láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ kẹ́míkà tàbí kọ̀m̀pútà.

Mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó àti iṣẹ́ abẹ ní ilé-ìwé gíga Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Yunifásitì Ilé-Ifẹ̀, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Mo ní àǹfààní ètò ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ láti ìlú ìbílẹ̀ mi, Ìpínlẹ̀ Oǹdó, ní gbogbo ìgbà tí mo wà ní ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó. Eléyìí mú mi lọ́kàn le ó sì fún mi ní ìwúrí láti sa gbogbo ipáàmi láti má ṣe pàdánù ètò ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ mi. Mo gba ìwé ẹ̀rí MSc nínú ìmọ̀ Clinical Pathology (ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ààrùn) láti ilé-ìwé gíga ìlú Èkó, lẹ́hìn náà mo ní ìmọ̀ nípa àwọn dókítà tí ń gbé ilé ìwòsàn lórí kẹ́míkà Pathology láti ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Yunifásitì ní ìlú Ilé-Ifẹ̀ àti lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí mo ń se ètò gbígba ìwé ẹ̀rí Ọ̀mọ̀wé (Phd) lórí ètò Mòlíkúlá Biology àti Genomics ní ilé-ìwé gíga Redeemers nílùú Ẹde, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun kan náà (ACEGID).

Ìfẹ́ mi sí ìgbáyé gbádùn àwọn obìnrin àti ọmọdé ló ṣokùnfà àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí mò ń ṣe lórí fífi ẹ̀kọ́ Metabolic Medicine àti Molecular Diagnostics wá ọ̀nà àbáyọ, èyí tó túmọ̀ sí lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ (sequencing ọjọ́ iwájú) àti Sáyẹ́ńsì Data láti ṣe ìpèsè ọ̀nà àbáyọ tí ìmọ̀ ìṣègùn tí yóò sì di ohun tí a le gbẹ́kẹ̀lé. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò tuntun ṣíṣe ìwádìí okùnfà ààrùn wọ̀nyí, ìtọ́jú ní kán-mó͎- ń kán-mọ́ tí ó sì péye yìí ó wà lárọwọ́tó, pẹ̀lú pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwárí tuntun tí ó ń yá mí lẹ́nu ló ń wáyé lóòrè kóòrè.

Kọ́ sí i nípa mi

Nígbà gbogbo ni ète kan wa fún ìwàláàyè wa. Ohun tí ó ń tì mí lọ́gbọn-ọ̀n-gbọ́n ni láti ṣe ìmúṣẹ ète mi èyí tí mo sì ń ṣe nípa títẹ̀lé ìdarí. Ẹnití ó ṣẹ̀dá ète mi àti èmi fún raà mi, ní ṣíṣẹ̀ ǹ tẹ̀lé.